Tuesday, 10 November 2020

IFA AWURE OSE MEJI

 Imi ojo, ewe ejinrin wewe, ewe isaju, ewe oyin, eyin adiye 1, ewe aje

Aogun papo pelu ose dudu,  aofi imi ojo tefa ose meji sori opon ifa re

Ofo re

Ao ha si lemeta, Ose meji iwo lose owo fun alara ti alara fi lowo lowo wa se owo temi funmi loni, iwo lose owo fun Ajero ti ajero fi wewu oye, wa sowo temi fun mi loni, Ose meji iwo lose owo fun Orangun Ile ila ti ofi gun ori ite baba re sowo,  wase owo temi funmi loni. Oju ki n mo ki Orunmila ma ni owo lowo, ejinrin loni ki owo wa rin momi, owo tinbe lowo okunrin ati eyi tinbe lowo obinrin, Ose meji ki owa se funmi ki o gba funmi loni. Ao da ifa yi si ose na ao po papo ao o ko sinu igba Olomori, odi wiwe Laro Laro.

Monday, 9 November 2020

ASEJE BIBO ASIRI NI KIA KIA

 ASEJE BIBO ASIRI NI KIA KIA.
Ao wa ewe tangiri oojo 16, ao wa ewe ola die, ao wa iyere 16, ao lo Gbogbo re papo, ao wa fi din eyin adie agric meta lepo niyo, tio bajina ao so kale Ao je kio tutu ao Se adua si,  ao koje.

IFA AWURE ASEJE IRETE ALAJE

 ASEJE AWURE IRETE ALAJE TODAJU
Odidi akuko adie funfun, ewe ina, ewe inabiri, ewe esisi, ewe aragba, ewe oloyin, ata ijosi, aolo papo aofise akouko adie yi je lepo niyo, isasun tuntun laofise, aoso si ori osuka,aofi iyere osun te ifa irete alaje. 

Ofore.....
Isan lawo erefe3x arobo lawo aijeun sun, alawo iyo nisawo ajegbin je karawun, awon ni won sefa fun ogberi okunrin tiwonpe ifa ni opuro, odifa fun ogberi obinrin tinpe esu ni yangi, orunmila sewon sila-sila, sewon siba-sibo wa bami, suna-suna lomode roko idi ina, kankan lewe ina jomo, warawara ni omode toko esisi bo, ile kogba won ona kogbawon lose ewe araagba, ojoti omode ba jawe oloyin aye, ojo na lonja tode orun, ojoti won bada iru ekun owo nlanla niwon finru ebo re loju opon, orunmila fi ona ile mi han olowo,oloro ileyii, bi akuko bako,afi ona han awon alejo.

Adua

Aoda iyere osun na sinu aseje naa,aowaro po aoje

Note,  gbogbo egungun re aoni run oo,aodasinu isasun naa, aoda awon ewe yen si, aofi odidi atare kan si aojopo aomafi oti lo larokutu.

Odaju

IFA AWURE OWO AGBOJO

 AWURE OWO AGBOOJO

Ao fi iyerosun tefa ejiogbe si owo wa osi, a o pe ofo yi si: ajifolayin oruko ti anpe ifa, ojini kutukutu ke gbami gbami ni oruko ti anpe iwo esu odara, akirijaowo ni oruko ti anpe eyin iya mi osoronga, owo to wa lokun, to wa losa, ko lo ba mi ja wal oni lowo awon enia rere, tokunrin ati tobinrin - a o fe si oju ojo, a o fi eyitoku sa ori wa ni owuro kutukutu, ni owuro lan lo ogun yi, o daju


THE TRUTH OF IFA

 This is a benevolence univese om this ifa says: A tree knot fears no rain Cast Ifa for OLODUMARE AGOTUN The ruler who created the well bala...